Isaiah 30

1“Ègbé ni àwọn ọmọ fún orílẹ̀-èdè alágídí,”
ni Olúwa wí,
“Fún àwọn tí ó gbé ètò jáde tí kì í ṣe tèmi,
tí wọ́n ń gbìmọ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nípa Ẹ̀mí mi,
tí wọ́n ń dá ẹ̀ṣẹ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀;
2tí wọ́n lọ sí Ejibiti
láìṣe fún mi,
tí ó ń wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Farao fún ààbò,
sí òjìji Ejibiti fún ibi ìsádi.
3Ṣùgbọ́n ààbò Farao yóò jásí ìtìjú fún un yín,
òjìji Ejibiti yóò mú àbùkù bá a yín.
4Bí àwọn olórí rẹ tilẹ̀ wà ní Ṣoani,
tí àwọn ikọ̀ wọn sì ti dé sí Hanisi,
5gbogbo wọn ni a ó dójútì,
nítorí àwọn ènìyàn kan tí kò wúlò fún wọn,
tí kò mú ìrànlọ́wọ́ tàbí àǹfààní wá,
bí kò ṣe àbùkù àti ìdójúti ni.”
6Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ sí àwọn ẹranko tí ó wà ní gúúsù:

Láàrín ilẹ̀ ìnira àti ìpọ́njú,
ti kìnnìún àti abo kìnnìún
ti paramọ́lẹ̀ àti ejò olóró,
àwọn ikọ̀ náà kó ẹrù àti ọrọ̀
wọn lẹ́yìn àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́,
àwọn ohun ìní wọn ní orí àwọn ìbákasẹ,
sí orílẹ̀-èdè aláìlérè,
7sí Ejibiti tí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
kò wúlò rárá.
Nítorí náà mo pè é ní
Rahabu aláìlẹ́ṣẹ̀ nǹkan kan.

8Lọ nísinsin yìí, kí o sì kọ ọ́ sí ara wàláà fún wọn,
tẹ̀ ẹ́ sí ara ìwé kíká,
pé fún àwọn ọjọ́ tí ó ń bọ̀
kí ó sì lè jẹ́ ẹ̀rí ayérayé.
9Àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ènìyàn
àti ẹlẹ́tanu ọmọ,
àwọn ọmọ tí wọn kò ṣetán láti tẹ́tí sí
ìtọ́ni Olúwa.
10Wọ́n sọ fún àwọn aríran pé,
“Ẹ má ṣe rí ìran mọ́!”
Àti fún àwọn wòlíì,
“Ẹ má ṣe fi ìran ohun tí ó tọ́ hàn wá mọ́!
Ẹ sọ ohun tí ó tura fún wa,
ẹ sàsọtẹ́lẹ̀ ẹ̀tàn.
11Ẹ fi ọ̀nà yìí sílẹ̀,
ẹ kúrò ní ọ̀nà yìí
ẹ dẹ́kun à ń dojú ìjà kọ wá
pẹ̀lú Ẹni Mímọ́ Israẹli!”
12Nítorí náà, èyí ni ohun tí Ẹni Mímọ́ Israẹli wí:

“Nítorí pé ẹ ti kọ ọ̀rọ̀ yìí sílẹ̀,
ẹ gbára lé ìnilára
kí ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀tàn,
13ẹ̀ṣẹ̀ yìí yóò rí fún ọ
gẹ́gẹ́ bí ògiri gíga, tí ó sán tí ó sì fì
tí ó sì wó lójijì, àti ní ìṣẹ́jú kan.
14Yóò sì fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́ bí àpáàdì
tí a fọ́ pátápátá
àti pé a kò ní rí ẹ̀rún kan nínú àfọ́kù rẹ̀,
fún mímú èédú kúrò nínú ààrò
tàbí gbígbọ́n omi jáde kúrò nínú àmù.”
15Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè, Ẹni Mímọ́ ti Israẹli wí:

“Nínú ìrònúpìwàdà àti ìsinmi ni ìgbàlà rẹ wà,
ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé ni agbára rẹ wà,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò ní ọ̀kankan nínú wọn.
16Ẹ̀yin wí pé, ‘bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò sálọ lórí ẹṣin.’
Nítorí náà ẹ̀yin yóò sá!
Ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa yóò gun àwọn ẹṣin tí ó yára lọ.’
Nítorí náà àwọn tí ń lé e yín yóò yára!
17Ẹgbẹ̀rún yóò sá
nípa ìdẹ́rùbà ẹnìkan;
nípa ìdẹ́rùbà ẹni márùn-ún
gbogbo yín lẹ ó sálọ,
títí a ó fi yín sílẹ̀
àti gẹ́gẹ́ bí igi àsíá ní orí òkè,
gẹ́gẹ́ bí àsíá lórí òkè.”

18Síbẹ̀síbẹ̀ Olúwa sì fẹ́ ṣíjú àánú wò ọ́;
ó dìde láti ṣàánú fún ọ.
Nítorí Olúwa jẹ́ Ọlọ́run ìdájọ́.
Ìbùkún ni fún gbogbo àwọn tí ó dúró dè é!
19Ẹ̀yin ènìyàn Sioni, tí ń gbé ní Jerusalẹmu, ìwọ kì yóò sọkún mọ́. Báwo ni àánú rẹ̀ yóò ti pọ̀ tó nígbà tí ìwọ bá kígbe fún ìrànlọ́wọ́! Bí ó bá ti gbọ́, òun yóò dá ọ lóhùn. 20Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Olúwa fún ọ ní àkàrà ìyà àti omi ìpọ́njú, àwọn olùkọ́ rẹ kì yóò fi ara sin mọ́; pẹ̀lú ojú rẹ ni ìwọ ó rí wọn. 21Bí o bá yí sápá ọ̀tún tàbí apá òsì, etí rẹ yóò máa gbọ́ ohùn kan lẹ́yìn rẹ, wí pé, “Ọ̀nà nìyìí, máa rìn nínú rẹ̀.” 22Lẹ́yìn náà ni ẹ ó ba àwọn ère yín jẹ́ àwọn tí ẹ fi fàdákà bò àti àwọn ère tí ẹ fi wúrà bò pẹ̀lú, ẹ ó sọ wọ́n nù bí aṣọ tí obìnrin fi ṣe nǹkan oṣù ẹ ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ kúrò níbí!”

23Òun yóò sì rọ òjò fún un yín sí àwọn irúgbìn tí ẹ gbìn sórí ilẹ̀, oúnjẹ tí yóò ti ilẹ̀ náà wá yóò ní ọ̀rá yóò sì pọ̀. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ẹran ọ̀sìn yín yóò máa jẹ koríko ní pápá oko tútù tí ó tẹ́jú. 24Àwọn màlúù àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí ó ń tú ilẹ̀ yóò jẹ oúnjẹ àdídùn tí a fi àmúga àti ṣọ́bìrì fọ́nkálẹ̀. 25Ní ọjọ́ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò sọ ẹ̀mí wọn nù nígbà tí ilé ìṣọ́ yóò wó lulẹ̀, odò omi yóò sàn lórí òkè gíga àti lórí àwọn òkè kékeré. 26Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

27Kíyèsi i, orúkọ Olúwa ti òkèèrè wá
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti kurukuru
èéfín tí ó nípọn;
ètè rẹ̀ kún fún ìbínú
ahọ́n rẹ̀ sì jẹ́ iná ajónirun.
28Èémí rẹ̀ sì dàbí òjò alágbára,
tí ó rú sókè dé ọ̀run.
Ó jọ àwọn orílẹ̀-èdè nínú kọ̀ǹkọ̀sọ̀;
ó sì fi sí ìjánu ní àgbọ̀n àwọn ènìyàn
láti ṣì wọ́n lọ́nà.
29Ẹ̀yin ó sì kọrin
gẹ́gẹ́ bí i ti alẹ́ tí ẹ̀ ń ṣe àjọyọ̀ àpéjọ mímọ́,
ọkàn yín yóò yọ̀
gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ènìyàn gòkè lọ pẹ̀lú fèrè
sí orí òkè Olúwa,
àní sí àpáta Israẹli.
30 Olúwa yóò jẹ́ kí wọn ó gbọ́ ohùn ògo rẹ̀
yóò sì jẹ́ kí wọ́n rí apá rẹ̀ tí ó ń bọ̀ wálẹ̀
pẹ̀lú ìbínú gbígbóná àti iná ajónirun,
pẹ̀lú mọ̀nàmọ́ná, àrá àti yìnyín.
31Ohùn Olúwa yóò fọ́ Asiria túútúú,
pẹ̀lú ọ̀pá aládé rẹ̀ ni yóò lù wọ́n bolẹ̀.
32Ẹgba kọ̀ọ̀kan tí Olúwa bá gbé lé wọn
pẹ̀lú ọ̀pá ìjẹníyà rẹ̀
yóò jẹ́ ti ṣaworo àti ti dùùrù,
gẹ́gẹ́ bí ó ti ń bá wọn jà lójú ogun
pẹ̀lú ìkùùkuu láti apá rẹ̀.
33A ti tọ́jú Tofeti sílẹ̀ tipẹ́tipẹ́,
a ti tọ́jú rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba.
Ojú ààrò rẹ̀ ni a ti gbẹ́ jì tí ó sì fẹ̀,
pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ iná àti igi ìdáná;
èémí Olúwa,
gẹ́gẹ́ bí ìṣàn sulfuru ń jó ṣe mú un gbiná.
Copyright information for YorBMYO